ÌJỌBA ṢÈYÍ MÁKINDÉ DI OYIN, Ẹ̀GÀN KÒ PÉ KÍ OYIN Ó MÁ DÙN LÉTÈ.

ÌJỌBA ṢÈYÍ MÁKINDÉ DI OYIN, Ẹ̀GÀN KÒ PÉ KÍ OYIN Ó MÁ DÙN LÉTÈ

Láti ọwọ́; Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Baba Awo
   Ayé fẹnu p'owó, owó ò tán, wọ́n fi bọ́tọ rẹ́'lé ilé tún ń ṣe rekete sí i, aró tí aṣèbàjẹ́ gbérò láti fi báṣọ jẹ́ níjọ́hun àná, ẹwà ló dà, ò sọ aṣọ dọ̀tun ni, èpè tí wọ́n mú sọ ìrókò, ara lolúwéré fi ń san. Òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀,aásà tí kò ní kánhún! 

  Ẹgbẹ́ alátakò ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ò mọ odó tí wọn ó kó ọ̀rúnlá dà sí mọ́, àṣeyọrí Ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti pò wọ́n nínú, ó jàn wọ́n nífun, ìṣèjọba Ọmọ 'Látúnbọ̀sún ti sọ wọ́n di dìndìnrìn kalẹ̀. Ọ̀pọ̀lọ́ wọn ti ṣìnà odò,àbòsí ni wọ́n fi ń koná jò, ìkòkò irọ́ ló kù tí wọ́n ń fojoojúmọ́ gbé kaná, wọ́n ń dá omi ìbàjẹ́ sí kòkò, wọ́n ń fi kèéta ṣe èèlò ọbẹ̀, ète ni wọ́n fi ń ṣe ṣíbí ti wọ́n fi ń ròó, ọbẹ̀ tí a  fi àbòsí koná ẹ̀ kìí jinná, ó ti ru paná, iná ti kú pi i! Ọbẹ̀ àbòsí ti dojú délẹ̀ nídìí ààrò!

 Irọ́ kàbìtì méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ẹni à ń wí gbé kalẹ̀ lópin ọ̀ṣẹ̀ tí a lò tán, lórí ètò ẹ̀kọ́, wọ́n gbé àbájáde ìgbéléwọ̀n àjọ Wàyẹ́ẹ̀kì(WAEC) arúmọjẹ jáde, nínú àtẹ irọ wọn, wọ́n ní Ipò kẹtàlélọ́gbọ̀n (33rd position) ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ wà, bí a ò bá gbàgbé, Ipò kọkàndínlọ́gbọ̀n(29th position) ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ rí mú,èyíun nì nígbà tí ẹgbẹ́ APC ń sèjọba, akitiyan Ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé lórí ètò ẹ̀kọ́ ló dá Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ padà sí ipò kọkànlá(11th position) nínú àbájáde àtẹ Ìgbéléwọ̀n tí àjọ Wàyẹ́ẹ̀kì ṣàgbéjáde gbẹ̀yìn, àṣeyọrí èyí ń bí wọn nínú jọjọ, ni wọn ṣe ń wọ̀nà ẹ̀bùrù láti wakọ̀ oríire yìí dànù. Òkòtó irọ́ ti bẹ́dìí, Gííwá àjọ Wàyẹ́ẹ̀kì ti jáde sí gbangba pé òtúbáńtẹ́ ní ìròyìn ipò kẹtàlélọ́gbọ̀n, irọ tó tún funfun báláú ni, Gííwá ní, àjọ Wàyẹ́ẹ̀kì kò tíì gbé àtẹ ìgbéléwọ̀n míràn jáde kọjá ti ìṣáájú, kí wọ́n yé si àwọn Olórí pípé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lọ́kàn. Lojú àwọn òpùrọ́ bá dá wápe, lẹnu bá ṣe bẹ́ẹ̀ ó rí dẹ̀dẹ̀rẹ̀!

  Ṣé ojoojúmọ́ ni inú abímọkú ń bàjẹ́, bó ṣe jẹ́ pé títí láé lẹkún alábòsí.
Ní kùtùkùtù òòjọ́ àbámẹ́ta òpin ọ̀sẹ̀, ni àwọn atúrọ́tà yìí bá tún gbé òmíràn dé,wọ́n ní gbogbo afárá òpópónà tuntun tó ń lọ lọ́wọ́ ní Ọ̀yọ́/Ìṣẹ́yìn, Mọ́níyà/Ìjàyè ní omi ti gbé lọ porogodo, wọ́n ń pariwo rara lórí ayélujára wọ́n ń sunkún egbére, àsé òtítọ́ ni pé ọ̀tá ẹni kìí p'òdù ọ̀yà? 
 
Òtítọ́ ìdí ọ̀rọ̀ yìí ni pé, àgbẹ̀ aládàáńlá kan ló kọ òkìtì dínà àgbàrá lójú ọ̀nà oko, eji ńlá dé, alagbalúgbú omi tí í ya ibú! Ọ̀pọ̀ òjò tí í ya'ko tí í ya'bè, òjò ò rọ́nà gbà mọ́ ló gba titi lọ, ẹ lọ wo àwòràn ọ̀hún fínnífínní, gbogbo afárá ló dúró 're, afárá kankan ò yinjẹ débi tí yó bá òjò rìn!

 Ṣebí isẹ́ ọ̀nà ọ̀hún sì ń lọ lọ́wọ́, ibi tó bá kù sí, agbasẹ́sé ni yó ṣe àtúnṣe, èyí kìí ṣe àkọ́kọ́ ariwo wọn, bí wọn ṣe pa á lórí pápá ìṣeré Adámásingbà rèé tí òjò rọ̀ lọ́jọ́ tí ìjọba ń sí abala kan nínú iṣẹ́ àkànse ọ̀hún, ní iṣẹ́ tí agbaṣẹ́se kò tíì yọ̀ǹda rẹ fún ìjọba, lọ́jọ́ òní ńkọ́, ẹ lọ wo pápá ìṣeré Lékan Sàlámì láì lábùkù kan,ariwo ìbàjẹ́ yín kò ní si àwọn ènìyàn rere ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lọ́nà!

 Ṣébí, bí ìyàwó ìyá ẹni bá ju ìyá ẹni lọ, ìyá làá pèé?! Kín ló dé tí ẹ ò gbà f'Ọ́lọ́run lórí akàndá ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ tó rán sí wa? Bí owó èrè orí epo tí ìjọba àpapọ̀ ṣe rí gọbọi lásìkò ìjọba àná, àáké lẹ yọ sí i, tẹ́ ẹ sá a t'eegun t'eegun, ìnira lẹ fi mú gbogbo mẹ̀kúnnù tòun tòsìsẹ́ ìjọba ilẹ̀ yìí, kí Olúwa ó tó fi ọmọ Mákindé tawá lọ́rẹ lásìkò ìpọ́njú, pé kó wá gbàwá lọ́wọ́ anúnidèfúnyà!

 Nínú òfíì, nínú ọ̀láà, lásìkò ọ̀dá owó tí owó tí ìjọba ń fi ránṣẹ́ kò jù béléńjá, Ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé ń ṣe bẹbẹ, ó ń gbé ribiribi ṣe, bó bá jẹ́ pé ẹgbẹ yín ló wà nípò lásìkò tí nǹkan ò fara rọ látàrí *àìkúnjú òsùnwọ̀n ìjọba àpapọ̀ àsìkò yìí* gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kò bá ti sá bá ilẹ̀ ibòmíràn lọ. Síbẹ̀, àwọn àṣeyọrí wọ̀nyí kò dùn mọ́ yín nínú, ẹ fẹ́ fi ìrọ òun àbòsí da ojú ọkọ̀ ìlọsíwájú ìpínlẹ̀ yìí dé, ẹ jẹ́ kó yé e yín pé àwọn Olóríire ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wẹ omi tútù wò wọ́n ti wẹ gbígbóná, wọ́n ti mọ ìyàtọ̀ nínú *iwọ òun òyin* , kí ẹ wá pẹ̀gan ìjọba yìí láti òní dàmọ́dùn, àwọn èèyàn rere ti mọ pé Oyin nìjọba tó ń bẹ lóde nìpínlẹ̀ yìí lọ́wọ́, *mọ̀nràhìn mọnranhin ló ń dùn létè !*

© *Ayélabẹ́gàn Akínkúnmi Baba Awo*
A Member, GSM Advocates
Ìwọ̀ Oòrùn Ọ̀yọ́,
Oyo West Local Government, Ọ̀yọ́ Aláàfin

Comments